
Lati Ọdọ AbdulHakeem Mutiu Adejumọ-Ajẹṣẹku, Ni Olu-ilu Naijiriya L’Abuja
Baba mi, oloogbe Alhaji Mutiu Alao Adejumọ-Ajẹṣẹku, lotitọ le ti d’oloogbe, sugbọn titi laelae ni iranti yin a maa wa ninu ọkan mi. Ẹyin ni iṣura mi, ẹyin ni alakoso mi, ẹyin ni ọrẹ mi, ẹyin ni amuyangan mi.
Mo mọ riri awọn ẹkọ ti ẹ kọ mi, awọn ẹrin poyẹkẹ-poyẹkẹ ti a jijọ rin, ati awọn oun maleegbagbe daadaa ti a jijọ ṣe. Ife ati ifarafun yin jẹ itọsọna fun mi. Mo ṣe afẹku yin, sugbọn mo ni itunu wipe orirun yin yoo tẹ siwaju lati ara mi gẹgẹ bi ikan ninu awọn ọmọ yin.
Baba mi, oloogbe Alhaji Mutiu Alao Adejumọ-Ajẹṣẹku, Ọmọ Iṣẹ Owo, Ọmọ Agba, Ọmọ Agbe, Ọmọ Okowodikuuku ruru, Ọmọ Ajagajigi, Ọmọ Oko Dun N Ko Re’le Mọ, Ọmọ Bi o Ja’we Kan Ẹgbaa Kan, Bi o Ja’we Meji Ẹgbaaji, Ọmọ Idowu, Ọmọ Adejumọ, Ọmọ Ọkanlọmọ, Ni’le Orogan-an, Ni Oke-Iro, L’Adatan, L’Ake, L’Ẹgba…
Ẹgba re yin, Ọmọ Ajibodu, Ọmọ Erin J’ogun Ọla, Ọmọ Abatabutu Ọlọrọ, Ọmọ Ahun Gbọn O K’ọmọ Ti Rẹ S’abẹ Ewe, Ogongo Nẹẹ Gbọn, O K’ọmọ Ti Rẹ S’abẹ Akitan, Olumọ Nẹẹ Gbọn, O K’ọmọ Ti Rẹ S’abẹ Apata Litori Ogun, Ọmọ Liṣabi Agbongbo Akala, Ọmọ Ajogbẹru Mama Jo Gbẹkọ, Litori Pe Ẹru Nii Sin’ni Ẹkọ Kii Sin’niyan, Ọmọ Ọṣilẹkun Palẹkunde, Ọmọ Aṣẹ Tii Mu’mi Kikan, Ọmọ Oro Tii Ke Yanmu-yanmu, Baba Ti yin L’aroyin Ogun Baara Fagbe, Ọmọ Ake Majo, Majojo Lọ Faa, O Jijo Lọ Faa O kuku Dide Ni, Ẹgba Ọmọ Oru Laa Ṣe’ka, Eniyan Re F’ọsan Ṣee Lijọsi, Olitohun Ko Fara ‘Re Lọ, Ọmọ Ẹgba Dudu Ko Si Ni’le, Pupa Yii Wa Li’le Ko Mọ Ọbe Se. Wọn Bi Yin L’Ake Ẹ Gbo L’ẹnu Bi Jẹjẹ, Wọn Bi Mi Li Gbagura Ẹ Gbolaya Bi Oje.
Edumare Ba Wa Da Ilu Ẹgba Si O. Aṣẹ Eledaa!
BABA MI, K’ỌLỌHUN ỌBA ALEKE ỌLA ṢE ỌGBA IDẸRA (ALUJANNA) NI IBUGBE YIN O. AAMEENAH YAA ALLAAH BI-JAAHI RASUULU LLAAHI (S.A.W)
Leave a comment